Kola Oyewo: Ó ti tó ọdún méje ti Kola Oyewo ti ń ṣàìsàn kó tó jáde láyé - Ẹbí

Àkọlé fídíò, Kola Oyewo: Ó ti tó ọdún méje ti Kola Oyewo ti ń ṣàìsàn kó tó jáde láyé - Ẹbí
Kola Oyewo: Ó ti tó ọdún méje ti Kola Oyewo ti ń ṣàìsàn kó tó jáde láyé - Ẹbí
Published

Agba oṣere tiata Yoruba to tun jẹ olukọ fasiti, Kola Oyewo ti jade laye.

Ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kejìlá oṣù kẹfà ọdún 2026 yìí ni ìròyìn ikú àgbà òṣèré náà gbà orí ayélujára kan.

Àwọn gbajúmọ̀ òṣèré bíi Kunle Afod ati Yomi Ọlọrunlaiye ni wọ́n ti ń daro ipapoda àgbà òṣèré náà.

Alẹ ọjọ Ẹti, ọjọ kejila, oṣu Karun un, ọdun 2026 yii ni awọn oṣere mii, Kunle Afod ati Yomi Ọlọrunlaiye kede iku rẹ.

Ọjọ́ kẹtadinlọgbọn oṣù kẹta ọdún 1946 ni olóògbé Kola Oyewo dele aye.

Ìlú Oba Ile nipinlẹ Osun tii ṣe ilu ibinibi rẹ to si tun ti jẹ oye Balogun ilu naa lo ku si.

O to ọjọ mẹta ti baba ti n ṣe aarẹ - Ọmọ Oloogbe

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ nigba ti a kan si ilu Ọba ile lẹyin ti iroyin iku agba oṣere naa jade, ọmọ oloogbe naa, Ọgbẹni Adewale Oyewọ ṣalaye pe o ti ṣe diẹ ti ojo ti n ṣe ogun agba oye Kọla Oyewọ bi o tilẹ jẹ wi pe ko le to eyi to fa iku rẹ yii.

Ninu ọrọ tirẹ, Ọgbẹni Yẹkini Shittu to jẹ olori ẹbi fun idile oloogbe naa ṣalaye pe akinkanju eeyan ni ti kofi ọrọ idile, ilu ati gbogbo awọn eeyan to yii ka ṣere rara.