Ìgboro dàrú n'Ilorin lẹ́yìn ìròyìn tó tàn kálẹ̀ pé àwọn agbébọn ti ya wọ àwọn ilé ẹ̀kọ́, ọlọ́pàá kìlọ̀

Awọn akẹkọọ to sa kuro nile ẹkọ lọ ile
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọrọ di bo o lọ ya n mi niluu Ilorin ti i ṣe olu ipinlẹ Kwara lonii ọjọ kejidinlogun, osu Kẹfa, lẹyin ti iroyin kan tan kalẹ pe awọn agbebọn ti ya wọlu, pe wọn si ti n ṣọsẹ nile ẹkọ kan ni agbegbe Oke-Oyi.

Lọgan lawọn alasẹ awọn ile-ẹkọ kan bẹrẹ sii gbe ile-ẹkọ wọn ti pa, bẹẹ lawọn olukọ mii n ransẹ si awọn obi ati awọn alagbatọ lati wa mu awọn ọmọ wọn lọ si ile.

Awọn ile-ẹkọ mii tilẹ da awọn akẹkọọ síta pe ki wọn maa sa lọ ile, ti awọn olukọ ati awọn akẹkọọ si n sa kijokijo.

Eyi lo fa Ibẹrubojo kaakiri ilu Ilorin ti ọpọ obi ati alagbatọ si n sare kaba kaba lọ mawọn ọmọ wọn nile ẹkọ.

A gbọ pe awọn obi kan ya bo awọn ile ẹkọ ti wọn kọ lati jọwọ awọn akẹkọọ wọn, lati mu awọn ọmọ wọn lọ sile ni tipa.

Iwadii fi han pe iroyin ẹlẹjẹ lo ni awọn agbebọn ti ya wọ ile ẹkọ - Ọlọpaa

Ẹwẹ, ajọ ọlọpaa Kwara ti fesi si ọrọ naa wi pe irọ ti o jina si ootọ ni iroyin to ni awọn agbesunmọmi ti ya wọ ilu.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Adetoun Ejire-Adeyemi, fi lede lo ti sọ pe ki awọn eeyan ma ṣe paya nitori iroyin ẹlẹjẹ lasan ni.

Adetoun sọ pe ni nnkan bii ago mẹsan-an kọja isẹju mẹẹdogun ni awọn gba ipe pajawiri wi pe awọn agbebọn ti ya wọ inu ọgba ile-ẹkọ girama awọn obinrin, Government Girls Secondary ni Oke-Oyi.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Lọgan ti a gbọ eyi ni agọ ọlọpaa Oke-Oyi ti ran awọn agbofinro lọ sibẹ lati daabo bo awọn akẹkọọ, olukọ ati awọn araalu.

"Iwadii fi han pe iroyin ẹlẹjẹ naa bẹrẹ nigba ti arabinrin kan ṣadeede sa wọ ile ẹkọ naa, to si n pariwo pe awọn agbebọn ti de si agbegbe naa.

"Iroyin ti wọn o sewadii lori rẹ yii lo fa rogbodiyan laaarin awọn olukọ ati awọn akẹkọọ, to si tun fa idaduro fun igbẹkọ fun igba ranpẹ.

"Fun idi eyi, iroyin naa kii se otitọ, ko si lẹsẹ nlẹ, a o kofiri agbesunmọmi kankan, ko si si ikọlu kankan ni Ipinlẹ Kwara,'' alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ṣalaye.

Adetoun sọ pe ọga agba ajọ ọlọpaa ni Kwara, Adekimi Ojo bẹnu atẹ lu titan iroyin ẹlẹjẹ ka, wi pe o le sokunfa rogbodiyan lawujọ.

O ni ajọ naa ti wa bẹrẹ igbesẹ lati da awọn ti wọn wa nidi ọrọ naa mọ, leyi ti wọn yoo pe wọn lati wa wi tẹnu wọn ti wọn yoo si jẹya ẹsẹ wọn labẹ bi ofin.

O rọ araalu ki wọn wa lojufo ṣugbọn ki wọn ṣe pẹlẹ, ki wọn si ma lọwọ ninu titan iroyin ẹlẹjẹ ka.

Agbẹnusọ naa sọ pe ajọ ọlọpaa Kwara ko ni kaarẹ nipa pipese aabo fun ẹmi ati dukia araalu.

Ẹwẹ, awọn obi kan ti wọn ba BBC Yoruba sọrọ ti wọn si bẹbẹ ki aforukọ bo awọn laṣirii ti sọ pe lati igba ti iṣẹlẹ Ogbomoso ti sẹlẹ ni awọn obi ti wa ni igbaradi nitori awọn o fẹ irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ ni ipinlẹ Kwara.

Awọn obi naa wa rọ ijọba pe ki wọn mu eto aabo awọn akẹkọọ ati ti ilu lapapọ lọkukudun, ki wọn si yara lati doola awọn akẹkọọ ati olukọ ti wọn ji gbe lọ ni Ogbomoso.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post