Ó pẹ́ tí mo ti sá kúrò nílé, mo rán ara mi ní fásitì, ọjọ́ kan làwọn òbí mi rí mi lórí Tẹlifísàn bíi gbajúmọ̀ akọrin - Shodey
Ni orilẹede Naijiria, orin takansufe ti a mọ si Hip-Pop ti di gbajumọ laarin awọn ọdọ, ti wọn si fi n gbe asa, ede ati ilẹ wa Naijiria ni arugẹ.
Ni agbo awọn akọrin takansufe naa, Araba nla, to n mi igbo kijikiji ni gbajumọ akọrin Shodade Solomon Segun, ti wọn tun mọ si Shodey.
O si tun jẹ Odu, ti kii se aimọ fun ọpọ ọdọ ti ọjọ orin wọn wa laarin ọdun mẹrindinlogun si ọgbọn ọdun, ti wn nifẹ si orin takansufe.
Ọmọbibi ipinlẹ Ogun ni akọrin naa amọ ilu Eko ni wọn ti tọ ọ dagba.
Nigba ti yoo fi di osu Kejila ọdun 2024, awọn eeyan to le ni miliọnu mọkandinlogun ti gbọ orin Shodey lor ẹrọ ayelujara ti wọn ti n gbe orin jade, eyi ta mọ si Sportify.
Koda, awọn to n gbọ orin Shodey ni osoosu le ni miliọnu kan eeyan.
Gẹgẹ bi ileesẹ to n gbe orin jade Sony Music nilẹ UK se se akọsilẹ rẹ, awọn ololufẹ to n tẹ le Shodey lẹyin, le ni ẹgbẹrun lọna ogoje .
Shodey, laipẹ yii si lo se abẹwo sile isẹ BBC to wa nilu Eko lati b awa takurọsọ, akojọpọ ohun ti a si sọ ree.

"Awọn ẹbi mi ko fi bẹẹ mọ nnkan ti mo n se amọ mo jẹ eeyan kan to maa n doju kọ afojusun ti mo ba ni"
Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Shodey salaye bo se rinrin aye rẹ, to fi di ilumọọka akọrin takansufe.
"O pẹ ti mo ti sa kuro nile, kuro lọdọ awọn obi mi, funra mi si ni mo da ran ara mi nile ẹkọ fasiti.
Awọn ẹbi mi ko fi bẹẹ mọ nnkan ti mo n se amọ mo jẹ eeyan kan to maa n doju kọ afojusun ti mo ba ni.
Awọn obi mi ko ri mi fun igba pipẹ, ọjọ kan ni wọn ri mi lori tẹlifisan pe mo ti di gbajumọ akọrin takansufe.
Emi kii se ẹni to maa n duro de ẹbi tabi ara, ki n to gbe igbesẹ fun aye ara mi.
Ohun ti mo fẹran ẹbi mi ni pe wọn maa n se iranwọ fun ohun ti mo ba fẹ se."
"Nigbakuugba ti mo ba n kọrin, bo se ila kan pere, maa fi ede Yoruba si tori ko si ibi ti a de laye, a gbọdọ gbagbe ibi ti a ti wa"
Shodey tẹsiwaju pe lati kekere ni oun ti mọ pe isẹ orin kikọ ni ọna atila oun amọ oun si ya bara sidi awọn isẹ miran.
"Mo bẹrẹ pẹlu ere ori itage, nigba to ya, mo tun se adẹrinposonu, nigba kan, mo tun n gbe eto jade lori ayelujara.
Mo mọ pe pẹlu gbogbo irinajo mi naa, maa si pada si idi orin tori orin kikọ jẹ nnkan t imo fẹran pupọ lati igba ti mo ti wa ni kekere.
Ko si bi eeyan se le kọ orin takansufe Hip-Pop to laye, a ko le kọ orin naa to awọn oyinbo nitori ede ti wọn ni wọn fi n kọ orin naa.
Wọn n gbe ede wọn larugẹ ni, gẹgẹ bii ọmọ Yoruba ti mo jẹ, ede temi ni wọn fẹ gbọ."
Gbajumọ akọrin takansufe naa ni ohun to mu oun yatọ sawọn olorin to ti n kọrin tẹlẹ ni lilo ede Yoruba, ti awọn oyinbo ko gbọ ri, iyẹn si ni orisun ati pataki orin oun.
"Nigbakuugba ti mo ba n kọrin, bo se ila kan pere, maa fi ede Yoruba si tori ko si ibi ti a de laye, ohun kan to se pataki ni ibi ti a ti wa, a ko si gbọdọ gbagbe ibi ti a ti wa.
O ya mi lẹnu pupọ pe orin mi ni itẹwọgba to ni, gẹgẹ bii akọrin to sẹsẹ n dide lẹ nigba yẹn.
Eyi lo fun mi ni idaniloju pe Ọlọrun fẹ ki n se isẹ yii, mo si ti gbe ọpọ awo orin sita eyi ti Ọlọrun n se ami si."
"N ko mọ pe orin Hey Jago le sọ mi di gbajumọ, ode ariya ni imisi orin naa ti wa si ọpọlọ mi, mo kan n sa eeyan kan ni"
Bakan naa, Shodey tan imọlẹ si ọna ti imisi orin Jago, to sọ ọ di gbajumọ akọrin, gba wa.
"Nipa orin Hay Jago, Jago kọ lo wa ba mi nipa orin ọhun, ni ọjọ kan, mo lọ si ode ariya, Poco Lee ati Jago wa nibẹ.
Wọn mu ina lọ, Poco Lee wa n pariwo Hey Jago, Hey Jago, kinni ọhun wa rẹwa leti mi, nigba ti mo dele, mo se orin Hey Jago sita.
Lẹyin igba diẹ, Jago ni ka se orin miran, a si se orin mii, orin tuntun ti a se ni mo ro pe a maa mu silẹ amọ nigba to ya, o kan si mi pe orin yii ni oun fẹ gbe sita.
Emi ko ni igbagbọ pe orin naa le ta, orin to jẹ pe a kan sa eeyan kan ni, bawo ni gbogbo orilẹede se fẹ loye nipa nnkan ta n se.
Amọ bo se jẹ itẹwọgba lọdọ awọn eeyan fihan pe ẹda kan maa sare ni, ọwọ Ọlọrun ni gbogbo rẹ wa."






