'Mo ti padà sí ẹsẹ̀ àárọ̀ lẹ́yìn tí mo sá kúrò ní South Africa'
'Mo ti padà sí ẹsẹ̀ àárọ̀ lẹ́yìn tí mo sá kúrò ní South Africa'
Published
Awọn ajoji ti wọn kuro ni South Africa nitori ikọlu awọn ọmọ orilẹ ede naa ti wọn n le awọn ajoji ti sọ iriri wọn leyin ti wọn pada si orilẹ ede wọn.
BBC News ba meji ninu awọn eeyan naa sọrọ ti wọn si sọ ohun ti oju wọn ti ri lati igba ti wọn ti pada sile.
Richard Itoro to pada si Naijiria sọ pe ibanujẹ ọkan lo jẹ fun oun nigba ti oun fẹ fi iyawo atawọn ọmọ oun silẹ.
O ni nnkan rọrun fun oun diẹ ki oun to ṣe irinajo lọ si South Africa amọ ti oun ko ni ohunkohun mọ nigba ti oun ti pada sile.
Bakan naa ni Emmanuel Asamoah to jẹ ọmọ orilẹ ede Ghana to ti bẹrẹ ọja tita lẹyin to pada si orilẹ ede rẹ sọrọ nipa ohun ti oun naa koju lẹyin to ti pada sile.



