Lónìí ni ètò ìdìbò Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun yóò wáyé

Oríṣun àwòrán, Najeem Salaam/Ademola Adeleke/Bola Oyebamiji/X
Oni ọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹjọ ni eto idibo gomina ipinlẹ Osun yoo waye.
Gbogbo eto lo ti to bayii fun eto idibo naa lati gberasọ.
Ṣaaju ni ajọ eleto idibo INEC ṣalaye oludibo to din diẹ ni miliọnu meji (1.9m) ni yoo kopa ninu eto idibo naa.
Lara awọn oludije ni Gomina Admola Adeleke ti ẹgbẹ oṣele Accord, Bola Oyebamiji ẹgbẹ APC ati Najeem Salaam ti ẹgbẹ ADC wa.
A o maa mu bi o ṣe n lọ wa fun yin loju opo wa yii.
