You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.

Take me to the main website

NÍ YÀJÓYÀJÓ, Àkójọpọ̀ ìròyìn bó ṣe ń lọ nínú ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti

Ìròyìn àtìgbàdégbà nípa ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

  1. Rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀ ní ibùdó ìdìbò, èèyàn kan farapa

    Rogbodiyan bẹ silẹ ni unit 4, woodu 2, oke omieja, Ilawe Ekiti to jẹ ibudo idibo ti Dare Bejide Oludije sipo gomina lẹgbẹ oṣelu African Democractic Congress ADC.

    Iṣẹlẹ ọhun da wahala diẹ silẹ loriko idibo naa, ki ibo didi to gberasọ ni pẹrẹu nibẹ.

    Olujide sipo gomina lẹgbẹ oṣelu ADC, Amb. Dare Bejide salaye pe lẹyin ti rogbodiyan naa waye loriko idibo oun.

    Bejide fẹsun kan awọn awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu APC fun lilọwọ ninu asa ibo rira.

    Bakan naa lo ke si awọn agbofinro ati ajọ eleto idibo INEC lati ṣewadii iṣẹlẹ naa.

    Lẹyin naa ni, Abayomi Shogunle, Kọmiṣanna ọlọpaa Ekiti sabẹwo si ibudo idibo naa ta w ani ilu Ilawe Ekiti lati fidi eto aabo mulẹ daadaa.

  2. Gómìnà Oyebanji tó ń dupò fún sáà kejì ti dìbò

    Gomina ipinlẹ Ekiti, Biodun Oyebanji, eni to n kopa nibi eto idibo naa fun saa keji ti dibo.

    Ni wọọdu kẹfa ni ilu Ikogosi ni Oyebanji ti dibo.

    Ninu ọrọ to ba awọn akọroyin sọ kẹyin ti di o tan, Gomina Oyebamiji sọ pe o da oun loju pe didun lọsan yoo so fun oun ninu ibo naa.

    Oyebamiji ṣalaye pe awọn iroyin to n tẹ oun lọwọ kaakiri ipinlẹ naa ti n fihan pe eto idibo n lọ nirọwọrọsẹ.

    Nigba ti awọn akọriyin bii pe ṣe o ṣi ni ireti pe yoo le ni ibo ẹẹdẹta ẹgbẹrun to jẹ afojusun rẹ lasiko to n ṣe ipolongo, gomina ipinlẹ Ekiti naa ni bi nnkan ṣe n lọ bayii o daju pe awọn yoo tayọ afojusun naa.

    Bakan naa lo tun sọ wi pé pẹlu bi iroyin tabo rabo ṣe n lọ kiri lasiko idibo yii, oun ko i tii gbọ iroyin kankan nitoun

  3. Olùdíje lẹ́gbẹ́ òṣèlú Accord, David Falegan náà ti dìbò

    Oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Accord, Opeyemi David Falegan ti dibo rẹ ni unit Idofin Ado Ekiti.

    Oludije ẹgbẹ oṣelu Accord ọhun sapejuwe eto idibo naa bi eyi ti ko lọ nibamu pẹlu alakalẹ eto idibo tori awọn oludibo kọọkan n gba ẹgbẹrun lọna ogun Naira lẹyin ibo didi.

    David Falegan bẹnu atẹ lu eto idibo naa pe ko ba ilana ijọba tiwa n tiwa mu.

  4. Olùdíje lẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP, Oluwole Oluyede fi èrò rẹ̀ hàn lórí ìbò náà

    Oludije dipo gomina lẹgbẹ oṣelu PDP l'Ekiti, Oluwole Oluyede ti dibo ni unit 3, wọọdu 6 niluu Ikere Ekiti.

    Oluyede gbarata nipa ifasẹyin to ba eto idibo ati wi pe awọn kan n dẹru ba awọn oludibo loriko eto idibo naa.

    Bakan naa lo ṣapejuwe eto idibo naa bi eyi ti ko jẹ itẹwọgba, tori pe iwọnba awọn oludibo lo raaye lati dibo wọn leyin wakati diẹ ti wọn ti wa ni ibudo idibo naa.

    Oluyede tun fẹsun kan pe awọn ọlọpaa n dẹru bawọn oludibo ni eyi to mu ki ọpọ awọn oludibo naa ma fẹ ẹ jade dabi alara.

    O sọ pe eto idibo naa ko tẹ oun lọrun, bẹẹ loun si ṣetan lati ṣafihan ẹri idaniloju ọrọ rẹ tasiko ba to.

  5. Etò òdìbò ti gbérasọ káàkiri ìpínlẹ̀ Ekiti

    Eto idibo ti bẹrẹ ni ipinlẹ Ekiti lati yan ẹni ti yoo di ipo gomina mu ni ipinlẹ naa fun saa ọlọdun mẹrin miran.

    Kaakiri awọn ibudo idibo ti ikọ BBC News Yorùbá kan si lawon ilu bii Ado Ekiti, Ilawẹ, Ikọgosi ati bẹẹ bẹẹ lọ lawọn oludibo ti jade lasiko lati dibo wọn.

    Ni ibudo idibo to wa ni ileẹko alakọbẹrẹ Odo Primary school ni wọọdu kẹwaa ni ileto Odo ni Ado Ekiti awọn oludibo kọminu lori bi awọn ẹrọ aṣayẹwo kaadi idibo BVAS ṣe n pẹ ko to ṣiṣẹ.

    Wọn rọ awọn alaṣẹ INEC lati wa nnkan ṣe si eyi ki idibo naa le lọ nirọwọrọsẹ.

    Ni unit7, ward 10 Okesa, nilu Ado Ekiti, eto iforukọsilẹ awọn oludibo ti gberaso.

    Awọn oṣiṣẹ agbofinro, oṣiṣẹ ajọ eleto idibo INEC, awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu pẹlu awọn oludibo tiwa nibi, bẹẹ ni nkan si n lọ ni mẹlọ mẹlọ.

    Ayafi bo se soro fawọn oludibo agbalagba kọọkan lati ṣawari orukọ wọn wo loju iwe tiwọn lẹ mọ ara ogiri.

    Awọn agbalagba ni wọn kọkọ da lohun lati tẹ ika

    Kehinde Boboye ati Grace Oguntinoye sọrọ wọn ni inu awọn dun lati jade wa dibo ṣugbọn wọn ko raaye se eto iforukọsilẹ oludibo.

  6. Ọlọ́pàá àtàwọn ọ̀dọ́ wọ̀yá ìjà, èèyàn kan kú àwọn ọ̀dọ́ dána sun àgọ́ ọlọ́pàá

    Niṣe ni ọrọ di bo o lọ yago fun mi ni ilu Isan Ekiti ni ìjọba ibilẹ Oye nipinlẹ Ekiti nigba ti wahala bẹ silẹ laaarin awọn ọlọpaa atawọn ọdọ ilu naa ti eeyan kan padanu ẹmi rẹ.

    Gẹgẹ bi ohun ti a ri gbọ aṣalẹ ọjọ Ẹti, ọjọ Kọkandinlogun, oṣu Kẹfa, ti eto idibo sipo gomina ipinlẹ Ekiti ku aarọ ni laasigbo naa waye.

    Ohun ta a rí gbọ ni pe ọlọpaa kan yinbon pa eeyan kan, ti eyi si mu kawọn ọdọ ilu naa yawọ ọfiisi ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Isan Ekiti, ti wọn si dana sun-un.

    Bakan naa, fọnran tí a rí lori ayelujara eyi ti aburo gomina tẹlẹri nipinlẹ Ekiti gbe síta safihan asiko ti awọn ọdọ naa yawọ ileeṣẹ ọlọpaa pẹlu ariwo pe awọn ko fẹ ọlọpaa mọ ni ilu naa.

    Ikọ BBC News Yoruba kan si ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ekiti lati fidi iṣẹlẹ naa mulẹ sugbọn ileeṣẹ ọlọpaa ni iroyin naa ko tii de ọdọ wọn.

    Akitiyan si n lọ lọwọ lati ba ileeṣẹ ọlọpaa sọrọ lori iṣẹlẹ naa.

  7. Ẹ kú ojúmọ́

    A ku ojumọ!

    BBC News Yoruba ti wa ni ipinlẹ Ekiti nibi ti eto idibo sipo gomina ipinlẹ naa ti n waye lonii.

    Ẹ maa bawa bọ bi a o ṣe maa mu awọn iroyin nipa ohun to n ṣẹlẹ ni ipinlẹ naa wa fun-un yin.