Ìjọba kéde owó orí lórí Búrédì ní Kogi, High Bread Price: Ẹgbẹ́ oníṣòwò búrẹ́dì yarí lórí gbígba owó orí lórí Búrẹ́dì
Iroyin kan to gbalẹ kan bayii ni pe ijọba yoo maa gba owo ori lori eroja burẹdi ti wọn ba se jade nipinlẹ Kogi.
Atẹjade tileesẹ to wa fun eto okoowo ati ileesẹ aje nipinlẹ Kogi fisita ni owo ori ọja lori burẹdi yoo mu ki owo to n wọle labẹle tubọ ru gọgọ si nipinlẹ naa.
Iroyin naa ni ijọba ti gba ileesẹ adani kan lati mu isẹ se lori igbesẹ naa, eyi ti yoo maa gba owo ori lọwọ awọn onileesẹ burẹdi lori awọn ọja ti wọn ba se jade.
Amọ sa, a gbọ pe ẹgbẹ awọn onisowo burẹdi nilẹ wa ti gbọnmu lori asẹ yii, ti wọn si n tako erongba ijọba naa, eyi ti wọn ni yoo fi ara ni wọn ati araalu lapapọ.
Awọn owo eroja burẹdi lo ti gbe ẹnu soke nilẹ Naijiria nitori owo gege tawọn eroja ti wọn fi n se ohun jijẹ naa, bii fulawa ati suga pẹlu awọn eroja miran, gbe lori.