Ìbọn tí wọ́n yìn sí ọkọ mi kò ràn án, ìgbà tí wọ́n gba àpò ọwọ́ rẹ̀ ni ìbọn tó ràn án – ìyàwó ọmọ ẹgbẹ́ Accord tí wọ́n pa l'Esa Oke ṣalàyé
Ìbọn tí wọ́n yìn sí ọkọ mi kò ràn án, ìgbà tí wọ́n gba àpò ọwọ́ rẹ̀ ni ìbọn tó ràn án – ìyàwó ọmọ ẹgbẹ́ Accord tí wọ́n pa l'Esa Oke ṣalàyé
Published
Awọn agbebọn yinbọn pa Ajayi Aderọgba ni ilu Ẹsa Oke ni ijba ibilẹ Obokun ni ipinlẹ Ọṣun.
Ohun ti ọpọ, yatọ si ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ naa n sọ ni pe iku oloogbe naa nii ṣe pẹlu ọrọ oṣelu.
Awọn ẹbi oloogbe naa ṣalaye fun BBC News Yoruba bi iku oloogbe naa ṣe waye.
Iyawo oloogbe Aderọgba to ṣalaye pe ẹgbẹ oṣelu Accord ni ọkọ oun n ṣe ki wọn to gbẹmi rẹ, n beere fun idajọ ododo bayii.
Arabinrin Tolulope Aderogba ṣalaye fun BBC News Yoruba pe Arakunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Ladapọ lo yinbọn si Aderọgba nigba ti ibọn naa ko ran an lo gba apo ọwọ rẹ to si mu nnkankan jade nibẹ ki o to wa yinbọn eyi to ran an.