Ìwádìí BBC tú àṣírí àwọn tó ń fi ajá tó ṣèse lú jìbìtì gbowó lórí ayélujára

Àkọlé fídíò, Ìwádìí BBC tú àṣírí àwọn tó ń fi ajá tó ṣèse lú jìbìtì gbowó lórí ayélujára
Ìwádìí BBC tú àṣírí àwọn tó ń fi ajá tó ṣèse lú jìbìtì gbowó lórí ayélujára

Aworan aja kan kọkọ farahan loju opo TikTok, aja naa wa ninu irora.

Ohun kan to n sọrọ labẹ fidio naa sọ pe aja ọhun ko sinu ijamba ọkọ kan, ẹni naa si rọ awọn eeyan ki wọn maa da owo jọ lati ṣe itọju rẹ.

Laarin ọsẹ diẹ ti fidio naa jade lori ayelujara lọjọ kẹjọ, oṣu Kinni, ọdun to kọja, eeyan bii mejila mii tun ti fi aja kan naa tọrọ owo.

Ẹnikan lati UK sọ orukọ aja ọhun ni Russet, eyii to n ṣafihan awọ aṣọ rẹ.

Ẹgbẹgbẹrun owo dọla lawọn eeyan ti da jọ fun itọju aja naa, sibẹsibẹ, ara aja naa ko da.

Ikọ oluwadii BBC Africa Eye ti ṣawari pe aja naa to wa ni Uganda jẹ eyii ti awọn eeyan kan fi n lu jibiti lati gba owo lọwọ awọn eeyan.

O ṣoro lati sọ ni pato ohun to ṣokunfa ijamba aja naa tabi ibi ti awọn apa ara rẹ ti wa.

Awọn to n lo aja naa ni Uganda n lo aanu ti awọn eeyan mii lagbaye ni fun aja lati fi ọna eburu gba wo lọwọ wọn.

Ninu iwadii BBC, aja naa wa niluu Mityana, to jẹ ibi ti awọn eeyan ti n ṣowo ni ọpọ kilomita siluu Kampala, to jẹ olu ilu Uganda.

Ilu ọhun gbajumọ fun didoola aja.

Charles Lubajja lasiko to n ba akọroyin wa sọrọ lai mọ pe akọroyin ni.

Awọn onijibiti n iUganda ti ri pe awọn eeyan nilẹ Europe, North America ati Australia fẹran aja, wọn si n lo ifẹ ti awọn eeyan naa ni fun aja lati mọọmọ maa gba owo lọwọ wọn.

Alaga ajọ to n daabo bo ẹranko ni Uganda, Bart Kakooza sọ fun BBC pe "Ọpọ awọn ọdọ ni Uganda lo n gbiyanju lati wa nnkan rere ṣe lori ayelujara.

"Fun awọn mii, wọn n lo ifẹ ti awọn eeyan nilẹ okeere ni fun aja lati lu wọn ni jibiti."

O ṣoro lati sọ ni pato iye oju opo ti wọn ṣi ni Mityana yii, amọ ọpọ oju opo bẹẹ lo ti wa ni Instagram, TikTok, Facebook ati YouTube nibi ti wọn ti n gbe aworan awọn ẹranko ti iya n jẹ lede ti wọn si n bere iranlọwọ fun itọju wọn.