''Ohun tó kàn fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ Oríire tó bọ́ lọ́wọ́ ajínigbé rèé, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ọ́...''

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/X
Onimọ nipa ero ọkan ẹda kan, Rhoda Abiola, ti ṣalaye ohun to kan fawọn akẹkọọ ijọba ibilẹ Oriire nipinlẹ Oyo ti wọn ṣẹṣẹ gbominira lọwọ ajinigbe.
Abiola sọ pe ti awọn obi ati awujọ ba kọ lati ṣe awọn nnkan naa fawọn akẹkọọ yii, iriri ti wọn ti ni ninu igbo yoo ni ipa to buru lori wọn titi aye.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Arabinrin Abiola sọ pe ''awọn obi awọn akẹkọọ to ṣẹṣẹ gbominira lọwọ ajinigbe ni iṣẹ to pọ lati ṣe nitori iriri ti wọn ni ninu igbo ti ṣakoba fun ilera ọpọlọ wọn.
Iya ti jẹ wọn, ebi ti pa wọn, ara ti ni wọn, wọn ti wa labẹ nnkan ti ko bawọn lara mu.
Awọn iriri yii ti maa jẹ ki wọn ni ero tuntun lori bi ile aye ṣe ri.
Ni ọpọ igba ti awọn ọmọde ba ni iru iriri to bani lẹru bi eleyii bii tawọn akẹkọọ Esinele ati Yawota, o maa n wa lori wọn titi aye ni.''
Arabinrin Abiola ṣalaye wi pe ọmọdẹ nilo aabo lati le gbagbọ pe ko si ewu foun ninu aye.
O fikun ọrọ rẹ pe ọmọde nilo ki wọn fi ifẹ han si i lati le gbagbọ pe ifẹ wa.
Amọ, Abiola ṣalaye pe iru awọn akẹkọọ ti wọn ji gbe nijọba ibilẹ Oriire l'Ogbomoso yoo maa ri ile aye bayii gẹgẹ bi ibi ti ko si aabo.
Onimọ nipa ero ọkan ẹda naa tun sọ pe awọn ọmọ Oriire ti wọn ji gbe yoo maa ri ile aye bayii gẹgẹ bii ibi to kun fun ewu tori iriri ti wọn ti ni ninu igbo.
''Awọn akẹkọọ yii nilo iranwọ awọn ẹbi wọn lasiko yii, o yẹ ki wọn pe awọn akọṣẹmọṣẹ nipa ero inu ẹda lati ba awọn ọmọ naa sọrọ ki wọn si sọ fun wọn pe aye yii si dara, ati pe ewu ko le hu wọn mọ.
Ti wọn ba ti gba idanilẹkọọ ati iranwọ yii tan ni ero wọn lori iriri ti wọn ni ninu igbo yoo yatọ.
Awọn obi wọn ni lati jẹ ki wọn mọ pe tibi tire ni a da ile aye.
Ẹni to ba gba ire lonii ko tumọ si pe ko le gba ibi ni ọjọ miran.
O tiẹ yẹ ki wọn maa dupẹ wi pe ẹmi wọn ko ba iṣẹlẹ naa lọ, tori ọpọ ninu wọn lo ti ku,'' Abiola lo sọ bẹẹ.
Onimọ nipa ero ẹda tun ṣalaye wi pe awọn obi wọn ni lati gbe awọn ọmọ naa lọ fun itọju ara ati ọkan wọn naa pẹlu.
Irufẹ itọju yii lawọn oloyinbo maa n pe ni ''Therapy.''
O tun fikun ọrọ rẹ pe awọn agbalagba to bọ lọwọ ajinigbe nilo igba diẹ ti ara wọn yoo fi ya daadaa.
Abiola sọ pe awọn agbalagba ti wọn ji gbe naa nilo itọju ''therapy'' ki ara wọn le ya daadaa.
O fikun ọrọ rẹ pe o rọrun fawọn agbalagba lati tete gbe iṣẹlẹ naa lara torí wọn ti ni ọpọlọpọ iriri nínú aye.
Wọ́n na àwọn ọmọdé tó wà nínú wa, wọ́n fi aṣọ dí wọn lẹ́nu, wọ́n fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ sí àwọn ọkùnrin lẹ́sẹ̀ - Arábìnrin Alamu
Arabinrin Rachael Folawe Alamu to ṣẹṣẹ gba itusilẹ lakata agbesunmọmi pẹlu awọn akẹkọọ rẹ ni ijọba ibilẹ Oriire nipinlẹ Oyo, ti sọ pe awọna gbesunmọmi naa na awọn ọmọ wẹwẹ to wa laarin wọn lasiko ti wọn wa ni igbekun.
Gẹgẹ bi obinrin naa ṣe sọ, awọn agbesunmọmi ọhun ko fẹran ariwo, amọ awọn ọmọde naa maa n pariwo lo jẹ ki wọn maa na wọn.
O ni lọpọ igba lawọn agbesunmọmi ọhun maa n fi aṣọ di ẹnu awọn ọmọde naa ki wọn ma ba a pariwo.
O ni "Fun emi o, wọn ko na mi, amọ wọn na awọn kan ninu awọn ọmọde to wa ninu wa.
"Awọn meji to kere ju ninu wọn, Waliya ati Salam, awọn ni wọn jẹ iya to pọju.
"Wọn maa bo ẹnu wọn, wọn fi aṣọ di wọn lẹnu, wọn si maa na wọn daadaa.
"Awọn ọkunrin to wa ninu wa ni tiwọn buru ju, wọn fi asọ boju wọn, fi ṣẹkẹṣẹkẹ si wọn lọwọ, wọn si maa wọn mọlẹ."


























