Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa àrùn Ebola tuntun

Àkọlé fídíò, Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa àrùn Ebola àti bí o ṣe lè dáàbò bo ara rẹ lọ́wọ́ àrùn náà
Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa àrùn Ebola tuntun
Published

Ṣé ẹ ti gbó pé ajọ to n ri si ọrọ ajakalẹ aarun ni ilẹ Africa ti kede pe wọn tun ti ṣawari ajakalẹ àrùn Ebola ẹ̀dá miran ni ilu Ituri, tó wá ni ẹkun ila oorun orilẹ ede Democratic Republic of Congo, DRC?

Ajọ Centres for Diseases Control and Prevention ni Africa, CDC sọ pe eeyan 246 ni wọn ti lugbadi alárùn Ebola Sudan tuntun bí a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí.

Bẹẹ, Èèyàn marundinlaadọrin (65) ni wọn ti dagbere fàyè ni agbegbe Mongwalu ati Rwanpara.

Àjọ World Health Organization (WHO) fidié mulẹ pé láti ara adan ni arun Ebola ti wa,

Àti pé O buru jọjọ nípasẹ̀ bo ṣe maa n gbẹmi eeyan laipẹ ọjọ.

Ẹranko bii Inaki, Adan ati Ẹgbin lo maa n ní Ebola tí wọn sì ń kóo ran eeyan.

Ebola maa n mu ki ọna ọfun dun eeyan, o tun maa n ṣadede fun eeyan ni iba lairo tẹlẹ.

Ti Ebola ba ti wọ ara eeyan lára tan, irufẹ ẹni bẹe yoo maa bi, yoo si maa ṣe igbọnsẹ gbuuru, nigba mii ẹni to ba ni Ebola yoo maa yọ ẹjẹ jade lati idi.

Laarin ọjọ meji pere si ọsẹ mẹta ni arun Ebola fi maa n dagba lara èèyàn.

Omi ara awọn to ba ni arun naa mas n tete gbẹ, eyii to maa n yọri si iku airotẹ́lé fún wọn

Ọdun 2014 ni arun naa milẹ titi julọ lagbaye nígbà tó ṣekú pá ẹgbẹrun mọkanla èèyàn.

BÁWO LÓ ṢE LÈ DÈNÀ EBOLA?

-- Maa fọ ọwọ rẹ pẹlu omi ati ọṣẹ ni gbogbo igba

-- Maṣe fi ọwọ rẹ kan ẹni to ba ti ko arun naa tẹlẹ tó sì ń gbà itọju lọ́wọ́

--Maṣe fi ọwọ tabi ara kan òkú enikankan lásìkò yii, paapaa ẹni ti o ko mọ irufẹ ohun to gbẹmi rẹ.

-- Ṣọra fun pipa, fifi ọwọ kan tabi jijẹ ẹran igbẹ láti òní lọ.

--- Abẹrẹ ajẹsara wa nigba kan ri fun ẹda Zaire arun Ebola amọ ko tii si abẹrẹ ajẹsara kankan fun ẹda Ebola Sudan tó gbòde kan bayii.

Wayi o, awọn onimọ ti sọ pe ẹni ti wọn ba tete ṣawari arun naa lara rẹ to si tètè gba itọju to peye le ru u la.

A kò ní rí ikú òjìji ó!

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images