2015 Elections: Àwòrán mánigbàgbé rèé tó sọ bí ìbò 2015 ṣe lọ

Published

Ọ̀pọ̀ ìsẹ̀lẹ̀ àríkọ́gbọ́n lo wáyé lásìkò ìbò 2015 nínú èyí tí ẹgbẹ́ alátakò ti gba ìjọba lọ́wọ́ ẹgbẹ́ tó darí Nàíjíríà fọ́dún mẹ́rìndínlógún.

Muhammadu Buhari, aya rẹ, Aisha, aya igbakeji aarẹ, Dọlapọ ati Yẹmi Ọsinbajo,igbakeji aarẹ
Àkọlé àwòrán, Lẹyin awọn ọkunrin to ba se aseyọri, awọn obinrin kan wa nibẹ́
Akanda ẹda kan ninu kẹkẹ n dibo
Àkọlé àwòrán, Ibo 2015 se pataki lara awọn ọmọ Naijiria, tawọn akanda ẹda gan ko si gbale joko
Buhari, Ibikunle Amosun ati Bola Ahmed Tinubu
Àkọlé àwòrán, Aaro mẹta ti kii da ọbẹ nu nipinl ogun lasiko ipolongo ibo aarẹ tẹgbẹ APC ldun 2015
Muhammadu Buhari to dije labẹ ẹgbẹ oselu APC ati Goodluck Jonathan to dije fẹgbẹ PDP di mọ ara wọn
Àkọlé àwòrán, Oselu ko yẹ ko mu ẹtanu lọwọ. Ere ọwọ lasan ni
Goodluck Jonathan n gbe akoso ijọba le Muhammadu Buhari lọwọ
Àkọlé àwòrán, Saa laa ni, ẹnikan ko nile aye. Bi igba kan ba lọ, igba miran yoo tun de
Awọn agbofinro n sọ oju popo
Àkọlé àwòrán, Ẹni ti yoo ba jẹun gbọ̀in-gbọin yoo tilẹkun gbọin-gbọin leto idibo 2015. Se lawọn agbofinro duro gbangba
Awọn agunbanirọ kan n yanju awọn ohun eelo idibo saaju idibo
Àkọlé àwòrán, Oriṣa ti ako ba fi oju ọmọde mọ ko ni pẹ parun. Awọn ọdọ to jẹ agunbanirọ ko gbẹyin ninu akoso ibo 2015
Ohun eelo idibo ti wọn lo ku ni agbala ileesẹ INEC
Àkọlé àwòrán, Ati okeere ni oloju jinjin ti n mu ẹkun sun lajọ INEC fi ibo 2015 se, ti ohun eelo idibo si to, o tun sẹkun si agbala wọn
Awọn oludibo sun lori iwe ikede ibo ti Buhari
Àkọlé àwòrán, Inu ẹni kii dun, ka paa mọra. Awọn oludibo kan ko lee pa iduunu wọn mọra lẹyin ti wọn kede ibo 2015
Awọn oludibo to sori ila lati dibo
Àkọlé àwòrán, Oju mẹwa ko jọ oju ẹni leto idibo 2015, tawọn eeyan ko si kọbi ara si oorun to mu yanyan, tabi jẹ ko sediwọ fun wọn lati dibo
Ẹnikan to gbe ikoko lori, mu igbalẹ lọwọ ati awo oju pẹlu orukọ APC lara wọn
Àkọlé àwòrán, Ipolongo ibo lọdun 2015 lo gba awọn ọna ara yọ, abi ki ni ka ti pe gbigbe ikoko lori pẹlu awo oju ati igbalẹ lọwọ lati dibo
Awọn ologun to di opopona kan lati sayẹwo ọkọ
Àkọlé àwòrán, Ẹni ti yoo ba esu jẹun, sibi rẹ yoo gun leto idibo 2015, tawọn ologun si gba arodan si igboro lati dẹkun rogbodiyan
Awọn osisẹ eleto idibo tan ina soju ni alẹ lati ka ibo
Àkọlé àwòrán, Irawe kii dajọ ilẹ ko sun ọna. Awọn osisẹ eleto idibo tan ina soju ni alẹ lati ka ibo ni
osisẹ eleto idibo kan wa lori ọkada pẹlu awn eroja idibo
Àkọlé àwòrán, Ba rọkọ, a ko reko, kii se ọrọ idibo 2015. Ibiti mọto ko de, wọn gbe ọkada de ibẹ lati pin ohun eelo idibo
Ọkinrin kan n se ayẹwo awọn iwe akọdsilẹ orukọ awọn oludibo
Àkọlé àwòrán, Ẹ bami wa orukọ mi, mo gbọdọ dibo loni ni. Ero yii lo seese ko maa wa lọkan arakunrin yii
Awọn oyinbo alawọ funfun to n tọpinpin ibo 2015
Àkọlé àwòrán, Oju gbogbo agbaye lo se mẹrin pẹlu idibo 2015