Coronavirus: Báyìí ni àwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ lórí rédíò ní Rwanda ṣe ń pín ìròyìn nípa ìmọ́tọ́tọ́ araẹni

Published

Awọn eeyan kan lorilẹ-ede Rwanda ti bẹrẹ si n ṣe ere ori redio lati kọ awọn olugbọ wọn nipa ṣiṣẹ imọtoto araẹni lasiko ajakalẹ arun Coronavirus.

Rwanda
Àkọlé àwòrán, Ẹre naa ma n de ọdọ awọn eeyan to le ni miliọnu mẹrin

Awọn ere ọhun ni wọn n ṣẹ pẹlu ajọṣẹpọ ajọ kan ti kii ṣe ti ijọba, ti orukẹ rẹ n jẹ "WaterAid" fun ọdun kan ati abọ.

Rwanda
Àkọlé àwòrán, Ọmọ ati iya wa lara awọn to n ṣe erer naa

Ayaworan kan, Elena Heatherwick lo n kọ itan naa, ti ileesẹ igbohunsafẹfẹ si ma fi sita fun eti igbọ awọn eeyan.

Rwanda
Àkọlé àwòrán, Ọdọmọde yii n tẹti si ẹgbọn rẹ to n kopa ninu ere naa lori redio

Ilẹ Rwanda lo kọkọ kede ofin konile-o-gbele nilẹ Afrika lẹyin ti arun ọhun rapala wọn orilẹ-ede naa lọjọ kejilelogun, oṣu kẹta ọdun 2020.

Rwanda
Àkọlé àwòrán, Awọn oṣere naa ma n ba ara wọn sọrọ ki wọn to bọ soju ọgbagadi

Awọn onwoye ọrọ to n lọ ti sọ pe ere ori redio ọhun n ko ipa to pọ ninu didẹkun arun naa nilẹ ọhun.

Rwanda
Àkọlé àwòrán, Evode ni yii, to jẹ ọmọ ogun ọdun, rengba rẹ ni lati jẹ gbajumọ oṣere

Redio jẹ ọna kan gboogi lati ṣe ikede lorilẹ-ede Rwanda niwọn igba ti eeyan kan ninu mẹrin ko lee kawe nilẹ ọhun.

Rwanda
Àkọlé àwòrán, Solongo niyii, ọdọ iya rẹ lo n gbe ni iha Ila-oorun Rwanda

Ere naa ma n de ọdọ miliọnu mrin eeyan o kere tan, eyi to jẹ ida mẹta awọn eeyan to wea lorilẹ-ede ọhun.

Rwanda
Àkọlé àwòrán, Sandrine niyii, o ni inu oun ma n dun ti oun gba ti n tẹti si ara oun lori redio
Rwanda
Àkọlé àwòrán, Emmanuel, ọmọ ọdun mẹtadinlogun
Rwanda
Àkọlé àwòrán, Solonge, Emelthe ati Danny n tẹti si ere naa lori redio
Rwanda
Àkọlé àwòrán, Wọn da aṣọ bo irinṣẹ ti wọn fi ka ere kalẹ nitori ojo